Mostrando postagens com marcador mejestade. Mostrar todas as postagens
Mostrando postagens com marcador mejestade. Mostrar todas as postagens

sábado, 23 de abril de 2022

ORIKI RARO DE ALÁÀFIN DE ÒYÓ, OBA LAMIDI ADEYEMI III

Postado por The Alaafin of Oyo

Em 23/04/2022




Kìnìún òkè Àkẹ̀sán, the lion on the hill of Akesan has finally ascended. When a god departs, the remaining gods must appease the land and the sky.

Rare Oriki of Aláàfin of Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Adeyemi III. The panegyric comes in part. Kindly take time and peruse as compiled by Abiola Jagunmolu, Oluokun Salman Abiodun from Baba Olanrewaju Adepoju 1974 renditions & translated by Toonday's Perspectives: #agrammartipaday ( yours truly ). May our good Lord bless Kabiyesi's soul with peaceful rest and overlook his shortcomings. Ameeeen.

Kìnìún òkè Àkẹ̀sán, Part 1
Séríkí olówó.
Ọmọ baba nígbà nígbà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n alákọ̀wé ọkọ. Abibatu.
Ọláyíwọlá di baba kò sé fi ọwọ́ rẹ́ ní'mú.
Àtàndá di òrìsà Ọ̀yọ́.
Ó di ẹni àjí f'ìlù kí.
Ẹni tí a ò sẹ́ tí a nfi ahọ́n pọ́nlẹ̀ lẹ̀ láá fún.
Egun sónsó tí parí iké.
Ọba tí mú ọba jẹ.
Ògìdán ìbẹ̀rù tí búú ramú-ramù ní kọ̀bì.
Ẹni Adéyẹmí bá bínú sí.
Kí olúwa ó káwọ́ ẹkún l'órí.
Ẹni Àtàndá bá nà'ka ìjà sí lójú.
Tí ò bá kánlu igbó kò ṣe nkankan.
Tí ò bá bẹ̀rù kánlu omi kí ṣe èwọ̀.
Ibi kìnìún bá tọ̀ọ̀ sí,
Ẹranko tí ó bá báá'bẹ̀ lọ ò s'oríre,
Ibi Àtàndá bá tutọ́ ìjà sí,
Ó ku baba ẹni tí ó rìn níbẹ̀.
Ìrònú ìkokò ní p'ajá,
Ìrònú ẹ̀yìn ọ̀rọ̀ ní p'èké,
Ìrònú ọlọ́rọ̀ ní p'ọ̀lẹ,
Ìpín àìsẹ̀ ní pá oní rìgímọ̀.
Ẹni Àtàndá bá f'ọwọ́ ìjà gùn ní'mú,
Olúwa rẹ̀ ló lùfin ọba,
Egun ẹran tí káyín olórí kunkun,
Òkèlè ràbàtà tí pinnu ọ̀kanjúà.
Àtàndá nṣe yín,
Ẹ n b'ọ̀sun,
Ẹ lọ sáré gb'ẹ́bọ fún iyemọja,
Bẹ́ẹ́, òrìsà bíbọ ò tánràn,
Èèyàn tí ó rúbọ,
Tí ò rúú ti Àtàndá,
Ara rẹ̀ ló tàn jẹ,
Ojú rere Ọláyíwọlá l'ẹbọ,
Àwàdà Àtàndá kọjá ètùtù.
Tí oní'fá bá n bọ'fá,
Kí wọn óo bọ ti ọmọ Ìbírónkẹ́ mọ́'fá,
Abọ̀rìsà tí n bọ̀'rìsà,
Kí ó máa bọ Lamidi,
Àtàndá ni eégún Ọ̀yọ́,
Ọláyíwọlá l'orò tí ngbé inú ààfin,
A tóbi nílé,
Tóbi l'óko,
Ògìdán fi ọwọ́ ìjà lalẹ̀.
Ìwà ọmọ ọkọ L'àtàndá ọmọ Alówólòdù nwù,
Ọláyíwọlá ò tàsé baba rẹ́ nínú ìwà Akin,
Adéyẹmí èèyàn nlá ọkọ Oyinlọlá.
Igijẹ́gẹ́dẹ́ ọba tí ó rí owó j'ayé ọba,
Ọ̀pádìjọ ìgbò,
Káríọlá kànnà-kan-tán-súá
Aborí ọmú dáranjẹ́ bámú-bámú,
Olówó eégún mọhuru,
Òròkí amọ́ lẹ́sẹ̀ bí òsùmàrè.
Ọ̀pádìjọ ìgbò,
Àtàndá náwó títí,
Owó ọ̀hún ò rántí,
Owó pọ̀ gẹ́ẹ́,
Owó kún odù,
Owó fa odù ya pẹrẹgẹrẹ bí aṣọ,
Ọ̀gọrọmitì tí náwó bí ẹlẹ́dà láyè àgbà.
Òkìkí owó kàn nílé,
Ayé ngbọ́ ariwo ọlà lẹ́yìn odi,
Ọjọ́ gbogbo bí ọdún,
Ọmọ Olúkúewu,
Àtàndá ọba oní fàájì.
Adéyẹmí ní káá kan ẹ̀tù,
Káá kan ààyá,
Káá kan ayaba,
Káá kan sòkòtò,
Káá kan ẹ̀wù,
Káá kan fìlà,
Káá kan ìkó Adé sí.
Abi ilé gbogbo ní jíjẹ mímu,
A fi ìgbà gbogbo rà bí ẹni tí n sọ̀wẹ̀,
Tún ayé ṣe,
Máa jẹ́ ó fọ́ọ́,
Irúmọlẹ̀ tí ngbé inú àpò pani jẹ,
Sànpọ̀nná ojú ìjà,
Tí k'ọmọ olódì n'ílà.
Adéyẹmí wọ́n ní o mọ́ ṣe oògùn ìkà mọ́,
O ní ò ṣe oògùn ìkà mọ́,
Èèè tijẹ́ Àtàndá,
O tún rán ìkan jẹ'lé èké lókè agúnpopo,
O tún nṣe ọsẹ bí-odó-bí-odó,
O tún nṣe ọsẹ bí-ọlọ-bí-ọlọ,
Èwo tún ní ọ̀kan gànnàkù tí ó ga bí ìdúró ènìyàn,
Èwo tún nìkan rìgìgbà tí nkọ lákùkọ ìsájú,
Igijẹ́gẹ́dẹ́ kínni o fi pamọ́ sílé tí ngbin bíí ẹbọra,
Kínni nbẹ lókè àjà tí tún fọhùn bí èèyàn.
Adéyẹmí ìgbò,
Àtàndá ìgbò,
Igijẹ́gẹ́dẹ́ ìgbò,
Káríọlá ìgbò,
Ọ̀pádìjọ ìgbò.
Kìnìún òkè Àkẹ̀sán,
Abi orí ẹṣin báábá lọ́nà kọ̀mu,
Abi ìrìn ẹṣin tìkọ̀-tìkọ̀ lọ́nà bààrà.
The Lion on the Hill of Akesan
Seriki the rich,
The son of a quotidian father
A learned sage the husband of Habibatu
Olayiwola becomes a father that cannot be slighted.
Atanda becomes Orisa Oyo.
He becomes the person to be adorned by dawning drum.
The person we didn't offend that we lick the humble ground for in reverence.
The cresting bone on hunchback
The king that crowns Kings
The fearsome that roars in the shrine
Who faces Adeyemi's wrath
The person should be in throes and cries
Whom Adeyemi points battle fingers at
If the person runs into the thick forest, that may be better
If the person out of fear rushes into the deep water that is not farfetched
Wherever a lion urinates
A prey that strays along that path is done for
Where Atanda spits his venom of battle
No one dares to walk the path
The fear of wolves bothers the dog
The fear of repercussion worries the gossiper
The fear of wealth burdens the lazy
Portion left undone bothers the hypocrite
Who Atanda challenges into a battle
The person falls under the wrath of the king
The stubborn bones that ends obstinate meal
The heavy morsel that devastates the greed
Atanda is your problem,
You are appeasing Osun
You are quick to sacrifice to the Mermaid
Yet worshipping gods won't exonerate you (from
Atanda's wrath )
He who makes sacrifice
Who doesn't appease Atanda
His strife is futile
Finding favour with Atanda is the sacrifice
A joke with Atanda surpasses sacrifice
When Ifa worshippers are doing their rites
They should make due recourse to the son of Ibironke
The Orisha Worshipper that performs the rites
Should worship Lamidi
Atanda the masquerade of Oyo
Olayiwola is the deity that dwells in Palace
A force at home
A force far and wide
A maestro that set the rules of battle
As a true son, Atanda the son of Alowolodu acts right,
Olayiwola acts the daring hero like his father
Adeyemi a great man, the husband of Oyinlola
The meek King that has the opulence and kingly luxury
The Uniting pole that holds the thicket as bunch
( Opadijo the man with brimming force)
Kariola the indefatigible philanthropist
The owner Mohuru masquerade
Oroki, who has freckleless legs like rainbow
The uniting pole that holds the thicket as a bunch
Atanda spends money till
Money couldn't keep tracks
Money so plenty
It fills container
It tears the container apart like cloth
The beast that spends without limit
The fame of his money spreads far and wide
The news of his wealth is known abroad
Everyday like festive
The son of Olukuewu
Atanda the king with luxury
Adeyemi has a roomful of gunpowder
A roomful of wives
A roomful of ayaba
A roomful of trousers
A roomful of tops
A roomful of caps
A roomful of crowns
His surroundings are for wining and feasting
He makes purchases like someone with unlimited fund
He makes the world a better place
Don't let it scattered
The god that dwells inside pocket to kill someone
The god of battle
That teaches fools the missing wisdom
Adeyemo, forewarned to desist from wicked charm
And you agreed not to do it
Why Atanda?
You sent termites to infest a hypocrite's house at the hill of Agunpopo
And you still cast spells like mortar like pestle
And you still cast spells like grindstone like stone.
Which one is that silhouette as tall as human
Which one is that robust that crows before the first cock
The meek one, what do you habour at home that breathes like a gnome.
What's in the raft that speaks like humans
Adeyemi the brimming force
Atanda the brimming force
The meek one the brimming force
Kariola the brimming force
Opadijo the brimming force
The lion on the hill of Akesan
Like the wanton horse's head along Komu
Like the horse walks sluggishly along Baara


Imagem comprobatório

TIKTOK ERICK WOLFF